4. OLUWA, gbogbo ọba ayé ni yóo máa yìn ọ́,nítorí pé wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.
5. Wọn óo sì máa kọrin nípa iṣẹ́ OLUWA,nítorí pé ògo OLUWA tóbi.
6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ga lọ́lá,ó ka àwọn onírẹ̀lẹ̀ sí,ṣugbọn ó mọ àwọn onigbeeraga lókèèrè.
7. Bí mo tilẹ̀ wà ninu ìpọ́njú,sibẹ, o dá mi sí;o dojú ìjà kọ ibinu àwọn ọ̀tá mi,o sì fi ọwọ́ agbára rẹ gbà mí.