6. ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lé orí omi,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae;
7. ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
8. Ó dá oòrùn láti máa ṣe àkóso ọ̀sán,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
9. Ó dá òṣùpá ati ìràwọ̀ láti máa ṣe àkóso òru,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.