Orin Dafidi 132:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà.

2. Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA,tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu,

3. tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi,bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi;

Orin Dafidi 132