Orin Dafidi 130:6-8 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Mò ń retí rẹ, OLUWA,ju bí àwọn aṣọ́de ti máa ń retí kí ilẹ̀ mọ́ lọ,àní, ju bí àwọn aṣọ́de, ti máa ń retí pé kí ilẹ̀ mọ́.

7. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ ní ìrètí ninu OLUWA!Nítorí pé ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ wà,ní ìkáwọ́ rẹ̀ sì ni ìràpadà kíkún wà.

8. Òun óo sì ra Israẹli pada kúrò ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

Orin Dafidi 130