Orin Dafidi 124:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wa,ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ wí pé,

2. “Tí kì í bá ṣe pé OLUWA tí ó wà lẹ́yìn wanígbà tí ọmọ aráyé gbógun tì wá,

3. wọn ìbá gbé wa mì láàyè,nígbà tí inú bí wọn sí wa;

4. àgbàrá ìbá ti gbá wa lọ,ìṣàn omi ìbá ti bò wá mọ́lẹ̀;

5. ìgbì omi ìbá ti gbé wa mì.”

6. Ọpẹ́ ni fún OLUWA,tí kò fi wá ṣe ẹran ìjẹ fún wọn.

Orin Dafidi 124