Orin Dafidi 119:8-22 BIBELI MIMỌ (BM)

8. N óo máa pa òfin rẹ mọ́,má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata.

9. Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni.

10. Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.

11. Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.

12. Ìyìn ni fún ọ, OLUWA,kọ́ mi ní ìlànà rẹ!

13. Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa.

14. Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́,bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.

15. N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ,n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ.

16. N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ,n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.

17. Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ,kí n lè wà láàyè,kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.

18. Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanutí ó wà ninu òfin rẹ.

19. Àlejò ni mí láyé,má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi.

20. Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo.

21. O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún,tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́.

22. Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi,nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́.

Orin Dafidi 119