Orin Dafidi 116:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nígbà náà ni mo ké pe OLUWA,mo ní, “OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí!”

5. Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA,aláàánú ni Ọlọrun wa.

6. OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́;nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí.

7. Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá,nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ.

8. Nítorí ìwọ OLUWA ti gba ọkàn mi lọ́wọ́ ikú,o gba ojú mi lọ́wọ́ omijé,o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú.

9. Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè.

Orin Dafidi 116