24. Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́,ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.”
25. Láti ìgbà laelae ni o ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,iṣẹ́ ọwọ́ rẹ sì ni ọ̀run.
26. Wọn óo parẹ́ ṣugbọn ìwọ yóo wà títí lae;gbogbo wọn yóo gbó bí aṣọ,o óo pààrọ̀ wọn bí aṣọ;wọn yóo sì di ohun ìpatì.
27. Ṣugbọn ìwọ wà bákan náà,ọjọ́ ayé rẹ kò sì lópin.
28. Ọmọ àwọn iranṣẹ rẹ yóo ní ibùgbé;bẹ́ẹ̀ ni arọmọdọmọ wọn yóo fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.