Orin Dafidi 102:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nítorí àwọn òkúta rẹ̀ ṣe iyebíye lójú àwọn iranṣẹ rẹ,àánú rẹ̀ sì ṣeni bí ó tilẹ̀ ti wó dà sinu erùpẹ̀.

15. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa bẹ̀rù orúkọ OLUWA,gbogbo ọba ayé ni yóo sì máa bẹ̀rù ògo rẹ̀.

16. Nítorí OLUWA yóo tún Sioni kọ́,yóo sì fara hàn ninu ògo rẹ̀.

17. Yóo gbọ́ adura àwọn aláìní,kò sì ní kẹ́gàn ẹ̀bẹ̀ wọn.

Orin Dafidi 102