Orin Dafidi 100:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA, gbogbo ilẹ̀ ayé.

2. Ẹ fi ayọ̀ sin OLUWA.Ẹ wá siwaju rẹ̀ pẹlu orin ayọ̀.

3. Ẹ mọ̀ dájú pé OLUWA ni Ọlọrun,òun ló dá wa, òun ló ni wá;àwa ni eniyan rẹ̀,àwa sì ni agbo aguntan rẹ̀.

Orin Dafidi 100