Nọmba 6:24-27 BIBELI MIMỌ (BM)

24. ‘Kí OLUWA bukun yín,kí ó sì pa yín mọ́.

25. Kí OLUWA mú kí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí yín lára,kí ó sì ṣàánú fún yín.

26. Kí OLUWA bojúwò yín,kí ó sì fún yín ní alaafia.’

27. “Bẹ́ẹ̀ ni wọn óo fi orúkọ mi súre fún àwọn ọmọ Israẹli, n óo sì bukun wọn.”

Nọmba 6