Nọmba 34:12-17 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Láti ibẹ̀ lọ sí ìhà gúsù lẹ́bàá odò Jọdani, yóo parí sí Òkun-Iyọ̀. Àwọn ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ yín.”

13. Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ óo fi gègé pín. Ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún àwọn ẹ̀yà mẹsan-an ààbọ̀ yòókù.

14. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ilẹ̀ tiwọn, tí a pín gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

15. ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko. Wọ́n sì ti pín in ní ìdílé-ìdílé.”

16. OLUWA sọ fún Mose pé,

17. “Eleasari alufaa ati Joṣua ọmọ Nuni ni yóo pín ilẹ̀ náà fun yín.

Nọmba 34