Nọmba 31:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Wọ́n gbógun ti àwọn ará Midiani gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, wọ́n sì pa gbogbo àwọn ọkunrin wọn.

8. Wọ́n pa àwọn ọba Midiani maraarun pẹlu. Orúkọ wọn ni: Efi, Rekemu, Suri, Huri ati Reba. Wọ́n pa Balaamu ọmọ Beori pẹlu.

9. Àwọn ọmọ Israẹli kó àwọn obinrin ati àwọn ọmọ Midiani lẹ́rú. Wọ́n kó gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo agbo ẹran wọn ati gbogbo ohun ìní wọn.

10. Wọ́n fi iná sun gbogbo ìlú wọn ati àwọn abúlé wọn,

11. wọ́n kó gbogbo ìkógun: eniyan ati ẹranko.

12. Wọ́n kó wọn wá sọ́dọ̀ Mose ati Eleasari ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ní òdìkejì odò Jọdani, lẹ́bàá Jẹriko.

13. Mose, Eleasari ati àwọn olórí jáde lọ pàdé àwọn ọmọ ogun náà lẹ́yìn ibùdó.

14. Mose bínú sí àwọn olórí ogun náà ati sí olórí ẹgbẹẹgbẹrun ati olórí ọgọọgọrun-un.

15. Ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ dá àwọn obinrin wọnyi sí?

16. Ṣé ẹ ranti pé àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu tí wọ́n sì mú àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA ní Peori, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni àjàkálẹ̀ àrùn ṣe bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli?

17. Nítorí náà ẹ pa gbogbo àwọn ọdọmọkunrin wọn, ati àwọn obinrin tí wọn ti mọ ọkunrin.

18. Ṣugbọn kí ẹ dá àwọn ọdọmọbinrin tí wọn kò tíì mọ ọkunrin sí, kí ẹ fi wọ́n ṣe aya fún ara yín.

Nọmba 31