Nọmba 28:9-13 BIBELI MIMỌ (BM)

9. “Ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ fi ọ̀dọ́ aguntan meji ọlọ́dún kan tí kò ní àbààwọ́n rú ẹbọ pẹlu idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún ẹbọ ohun jíjẹ pẹlu ẹbọ ohun mímu.

10. Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun yìí ní gbogbo ọjọ́ ìsinmi pẹlu ẹbọ ojoojumọ ati ẹbọ ohun mímu.

11. “Ẹ óo máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù. Àwọn nǹkan tí ẹ óo máa fi rúbọ ni: ọ̀dọ́ akọ mààlúù meji ati àgbò kan ati ọ̀dọ́ àgbò meje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí kò ní àbààwọ́n.

12. Fún ẹbọ ohun jíjẹ, ẹ lo ìdámẹ́wàá mẹta ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa, tí a fi òróró pò fún akọ mààlúù kan ati idamẹrin ìyẹ̀fun òṣùnwọ̀n efa tí a fi òróró pò fún àgbò kan.

13. Ati ìdámẹ́wàá òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò fún ọ̀dọ́ aguntan kan. Èyí jẹ́ ẹbọ sísun olóòórùn dídùn fún OLUWA.

Nọmba 28