9. Ẹ má lòdì sí OLUWA, ẹ má sì bẹ̀rù àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà. A óo ṣẹgun wọn, nítorí kò sí ààbò fún wọn mọ́. OLUWA wà pẹlu wa, ẹ má bẹ̀rù.”
10. Bí àwọn eniyan náà ti ń gbèrò láti sọ wọ́n lókùúta pa ni wọ́n rí i tí ògo OLUWA fara hàn ní Àgọ́ Àjọ.
11. OLUWA sọ fún Mose pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo ti kọ̀ mí sílẹ̀ pẹ́ tó. Yóo ti pẹ́ tó kí wọ́n tó máa gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn?
12. N óo rán àjàkálẹ̀ àrùn láti pa gbogbo wọn run, n óo sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, ṣugbọn n óo sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè tí yóo pọ̀ ju àwọn wọnyi lọ, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.”
13. Mose bá sọ fún OLUWA pé, “Ní ààrin àwọn ará Ijipti ni o ti mú àwọn eniyan wọnyi jáde pẹlu agbára. Nígbà tí wọn bá sì gbọ́ ohun tí o ṣe sí wọn, wọn yóo sọ fún àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ yìí.