Nọmba 10:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Netaneli ọmọ Suari ni olórí ẹ̀yà Isakari.

16. Olórí ẹ̀yà Sebuluni sì ni Eliabu ọmọ Heloni.

17. Nígbà tí wọ́n tú Àgọ́ Àjọ palẹ̀, àwọn ọmọ Geriṣoni ati àwọn ọmọ Merari tí ó ru Àgọ́ Àjọ náà ṣí tẹ̀lé àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Juda.

Nọmba 10