33. Sibẹ, o jàre gbogbo ohun tí ó dé bá wa yìí, nítorí pé o ṣe olóòótọ́ sí wa, àwa ni a hùwà burúkú sí ọ.
34. Àwọn ọba wa, ati àwọn ìjòyè wa, àwọn alufaa wa ati àwọn baba wa kọ̀, wọn kò pa òfin rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tẹ̀lé ìlànà rẹ, wọn kò sì gbọ́ ìkìlọ̀ rẹ. Pẹlu, bí àwọn nǹkan rere tí o fún wọn ti pọ̀ tó, lórí ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì dára tí o fún wọn.
35. Wọn kò sìn ọ́ ní agbègbè ìjọba wọn, ati ninu oore nla rẹ tí o fun wọn, àní ninu ilẹ̀ ẹlẹ́tù lójú nla tí o bùn wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì yipada kúrò ninu iṣẹ́ burúkú wọn.