68. àwọn ìbaaka wọn jẹ́ ojilerugba ó lé marun-un (245),
69. àwọn ràkúnmí wọn jẹ́ ojilenirinwo ó dín marun-un (435), àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sì jẹ́ ẹgbaata ó lé ọrindinlẹgbẹrin (6,720).
70. Àwọn olórí ní ìdílé kọ̀ọ̀kan kópa ninu iṣẹ́ náà. Gomina fi ẹgbẹrun (1,000) ìwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati aadọta àwo kòtò, ati ẹẹdẹgbẹta ó lé ọgbọ̀n (530) ẹ̀wù alufaa sí i.
71. Àwọn kan ninu àwọn baálé baálé fi ọ̀kẹ́ kan (20,000) òṣùnwọ̀n diramu wúrà sí ilé ìṣúra ati ẹgbọkanla (2,200) òṣùnwọ̀n mina fadaka.