Nehemaya 7:21-32 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Àwọn ọmọ Ateri tí wọn ń jẹ́ Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un.

22. Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ ọọdunrun ó lé mejidinlọgbọn (328).

23. Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹrinlelogun (324).

24. Àwọn ọmọ Harifi jẹ́ aadọfa ó lé meji (112).

25. Àwọn ọmọ Gibeoni jẹ́ marundinlọgọrun-un.

26. Àwọn ará Bẹtilẹhẹmu ati Netofa jẹ́ ọgọsan-an ó lé mẹjọ (188).

27. Àwọn ará Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128).

28. Àwọn ará Beti Asimafeti jẹ́ mejilelogoji.

29. Àwọn ará Kiriati Jearimu ati Kefira ati Beeroti jẹ́ ọtadinlẹgbẹrin ó lé mẹta (743).

30. Àwọn ará Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta lé mọkanlelogun (621).

31. Àwọn ará Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122).

32. Àwọn ará Bẹtẹli ati Ai jẹ́ mẹtalelọgọfa (123).

Nehemaya 7