9. Mo bá tọ àwọn gomina ìgbèríko òdìkejì odò lọ mo fún wọn ní lẹta tí ọba kọ. Ọba rán àwọn olórí ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tẹ̀lé mi.
10. Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ará Horoni ati Tobaya iranṣẹ ọba, ará Amoni gbọ́, inú bí wọn pé ẹnìkan lè máa wá alaafia àwọn ọmọ Israẹli.
11. Mo bá wá sí Jerusalẹmu mo sì wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.
12. Mo gbéra ní alẹ́ èmi ati àwọn eniyan díẹ̀, ṣugbọn n kò sọ ohun tí Ọlọrun mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe ní Jerusalẹmu fún ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹranko kankan pẹlu mi àfi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn.
13. Mo gbéra lóru, mo gba Ẹnubodè Àfonífojì. Mo jáde sí kànga Diragoni, mo gba ibẹ̀ lọ sí Ẹnubodè Ààtàn. Bí mo ti ń lọ, mò ń wo àwọn ògiri Jerusalẹmu tí wọ́n ti wó lulẹ̀ ati àwọn ẹnu ọ̀nà tí wọ́n ti jó níná.
14. Lẹ́yìn náà, mo lọ sí Ẹnubodè Orísun ati ibi Adágún ọba, ṣugbọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn kò rí ọ̀nà kọjá.