17. Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo ní, “Irú nǹkan burúkú wo ni ẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi?
18. Irú nǹkan burúkú yìí kọ́ ni àwọn baba yín pàápàá ṣe tí Ọlọrun fi mú kí ibi bá àwa ati ìlú yìí? Sibẹ, ẹ tún ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi, ẹ̀ ń fa ìrúnú Ọlọrun sórí Israẹli.”
19. Nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣú ní àwọn Ẹnubodè Jerusalẹmu kí ó tó di ọjọ́ ìsinmi, mo pàṣẹ pé kí wọ́n ti gbogbo ìlẹ̀kùn, ati pé wọn kò gbọdọ̀ ṣí i sílẹ̀ títí tí ọjọ́ ìsinmi yóo fi rékọjá. Mo yan díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ mi sí àwọn ẹnubodè náà, kí wọ́n má baà kó ẹrù kankan wọlé ní ọjọ́ ìsinmi.