8. Jerusalẹmu, ìwọ ilé ìṣọ́ agbo aguntan Sioni, ilé ọba rẹ àtijọ́ yóo pada sọ́dọ̀ rẹ, a óo dá ìjọba pada sí Jerusalẹmu.
9. Kí ló dé, tí ò ń pariwo bẹ́ẹ̀? Ṣé ẹ kò ní ọba ni? Tabi ẹ kò ní olùdámọ̀ràn mọ́, ni ìrora fi mu yín bí obinrin tí ń rọbí?
10. Ẹ máa yí nílẹ̀, kí ẹ sì máa kérora bí obinrin tí ń rọbí, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu; nítorí pé ẹ gbọdọ̀ jáde ní ìlú yín wàyí, ẹ óo lọ máa gbé inú pápá; ẹ óo lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni a óo ti gbà yín là, níbẹ̀ ni OLUWA yóo ti rà yín pada kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.
11. Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè dojú ìjà kọ yín nisinsinyii, wọ́n sì ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á sọ Sioni di aláìmọ́, kí á sì dójúlé e.”
12. Ṣugbọn àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò mọ èrò OLUWA, ìpinnu rẹ̀ kò sì yé wọn, pé ó ti kó wọn jọ láti pa wọ́n bí ẹni pa ọkà ní ibi ìpakà.