7. A óo dójúti àwọn aríran, ojú yóo sì ti àwọn woṣẹ́woṣẹ́; gbogbo wọn yóo fi ọwọ́ bo ẹnu wọn, nítorí pé, Ọlọrun kò ní dá wọn lóhùn.
8. Ṣugbọn ní tèmi, mo kún fún agbára, ati ẹ̀mí OLUWA, ati fún ìdájọ́ òdodo ati ipá, láti kéde ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli fún wọn.
9. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, ati ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli, ẹ̀yin tí ẹ kórìíra ìdájọ́ òdodo, tí ẹ sì ń gbé ẹ̀bi fún aláre.
10. Ẹ̀yin tí ẹ fi owó ẹ̀jẹ̀ kọ́ Sioni, tí ẹ sì fi èrè ìwà burúkú kọ́ Jerusalẹmu.