Mika 2:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ègbé ni fún àwọn tí wọn ń gbìmọ̀ ìkà, tí wọ́n sì ń gbèrò ibi lórí ibùsùn wọn. Nígbà tí ilẹ̀ bá sì mọ́, wọn á ṣe ibi tí wọn ń gbèrò. Nítorí pé ó wà ní ìkáwọ́ wọn láti ṣe é.

2. Bí ilẹ̀ kan bá wọ̀ wọ́n lójú, wọn á gbà á lọ́wọ́ onílẹ̀; bí ilé kan ló bá sì wù wọ́n, wọn á fi ipá gbà á lọ́wọ́ onílé; wọ́n ń fìyà jẹ eniyan ati ilé rẹ̀, àní eniyan ati ohun ìní rẹ̀.

3. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí; ó ní, “Wò ó, mò ń gbèrò ibi kan sí ìdílé yìí; tí ẹ kò ní lè bọ́rí ninu rẹ̀; ẹ kò ní rìn pẹlu ìgbéraga, nítorí pé àkókò burúkú ni yóo jẹ́.

4. Ní ọjọ́ náà, wọn yóo máa fi yín kọrin ẹlẹ́yà, wọn yóo sì sọkún le yín lórí tẹ̀dùntẹ̀dùn. Wọn yóo wí pé, ‘A ti parun patapata; ó ti pa ìpín àwọn eniyan mi dà; ẹ wò bí ó ti yí i kúrò lọ́dọ̀ mi, ó pín ilẹ̀ wa fún àwọn tí wọ́n ṣẹgun wa.’ ”

5. Nítorí náà kò ní sí ìpín fún ẹnikẹ́ni ninu yín mọ́ nígbà tí a bá dá ilẹ̀ náà pada fún àwọn eniyan Ọlọrun.

6. Àwọn eniyan náà ń pàrọwà fún mi pé, “Má waasu fún wa. Kò yẹ kí eniyan máa waasu nípa irú nǹkan báwọ̀nyí, Ọlọrun kò ní dójútì wá.

Mika 2