1. “Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀sìn yín, ẹ má máa hùwà ṣe-á-rí-mi, kí àwọn eniyan baà lè rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe. Bí ẹ bá ń hùwà ṣe-á-rí-mi, ẹ kò ní èrè lọ́dọ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.
2. “Nítorí náà, nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe gbé agogo síta gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣehàn tí ń ṣe ninu àwọn ilé ìpàdé ati ní ojú títì ní ìgboro, kí wọn lè gba ìyìn eniyan. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
3. Ṣugbọn nígbà tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má tilẹ̀ jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe;
4. kí ìtọrẹ àánú rẹ jẹ́ ohun ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀ yóo sì san ẹ̀san rẹ fún ọ.
5. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má ṣe bí àwọn aláṣehàn. Nítorí wọ́n fẹ́ràn kí wọ́n máa dúró gbadura ninu ilé ìpàdé ati ní ẹ̀bá títì, kí àwọn eniyan lè rí wọn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, wọ́n ti gba èrè wọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
6. Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbadura, wọ inú yàrá rẹ lọ, ti ìlẹ̀kùn rẹ, kí o gbadura sí Baba rẹ tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀. Baba rẹ, tí ó rí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, yóo san ẹ̀san rẹ fún ọ.
7. “Nígbà tí ẹ bá ń gbadura, ẹ má máa wí nǹkankan náà títí, bí àwọn abọ̀rìṣà ti ń ṣe. Nítorí wọ́n rò pé nípa ọ̀rọ̀ pupọ ni adura wọn yóo ṣe gbà.
8. Ẹ má ṣe fara wé wọn, nítorí Baba yín ti mọ ohun tí ẹ nílò kí ẹ tó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
9. Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura:‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run:Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ,
10. kí ìjọba rẹ dé,ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayébí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run.
11. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí.
12. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wágẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá.
13. Má fà wá sinu ìdánwò,ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’