28. “Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn gúnnugún yóo péjọ sí.
29. “Lẹsẹkẹsẹ lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́ láti ọ̀run. Gbogbo àwọn agbára tí ó wà ní ọ̀run ni a óo mì jìgìjìgì.
30. Àmì Ọmọ-Eniyan yóo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ayé yóo figbe ta, wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí ó ń bọ̀ lórí ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbára ògo ńlá.
31. Yóo wá rán angẹli rẹ̀ pẹlu fèrè ńlá, wọn yóo kó àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ jọ láti igun mẹrẹẹrin ayé; àní láti ìkangun ọ̀run kan dé ìkangun keji.
32. “Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ, tí ó bá bẹ̀rẹ̀ sí rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí.