5. Ṣugbọn wọn kò bìkítà. Ọ̀kan lọ sí oko rẹ̀, òmíràn lọ sí ìdí òwò rẹ̀.
6. Àwọn ìyókù ki àwọn ẹrú mọ́lẹ̀, wọ́n lù wọ́n pa.
7. Inú wá bí ọba náà, ó bá rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ kí wọ́n pa àwọn apànìyàn wọ̀n-ọn-nì run, kí wọ́n sì dáná sun ìlú wọn.
8. Ó bá sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘A ti parí gbogbo ètò igbeyawo, ṣugbọn àwọn tí a ti pè kò yẹ.
9. Ẹ wá lọ sí gbogbo oríta ìlú, ẹ pe gbogbo ẹni tí ẹ bá rí wá sí ibi igbeyawo.’
10. Àwọn ẹrú náà bá lọ sí ìgboro, wọ́n kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí wá, ati àwọn eniyan rere, ati àwọn eniyan burúkú. Oniruuru eniyan bá kún ibi àsè igbeyawo.
11. “Nígbà tí ọba wọlé láti wo àwọn tí wọn ń jẹun, ó rí ọkunrin kan níbẹ̀ tí kò wọ aṣọ igbeyawo.