28. “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí ẹrù ìpọ́njú ń wọ̀ lọ́rùn. Èmi yóo fun yín ní ìsinmi.
29. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onírẹ̀lẹ̀ ati ọlọ́kàn tútù ni mí, ọkàn yín yóo sì balẹ̀.
30. Nítorí àjàgà mi tuni lára, ẹrù mi sì fúyẹ́.”