26. Bí Satani bá gbógun ti ara rẹ̀, tí ó ń bá ara rẹ̀ jà, kò lè fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, a jẹ́ pé ó parí fún un.
27. “Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè wọ ilé alágbára kan lọ, kí ó kó dúkìá rẹ̀ láìjẹ́ pé ó kọ́ de alágbára náà mọ́lẹ̀, nígbà náà ni yóo tó lè kó ilé rẹ̀.
28. “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a óo dárí ji àwọn ọmọ eniyan, ati gbogbo ìsọkúsọ tí wọ́n lè máa sọ.
29. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò lè ní ìdáríjì laelae, ṣugbọn ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ títí lae.”
30. (Jesu sọ èyí nítorí wọ́n ń wí pé ó ní ẹ̀mí Èṣù.)