14. Ó bá yan àwọn mejila, ó pè wọ́n ní aposteli, kí wọn lè wà pẹlu rẹ̀, kí ó lè máa rán wọn lọ waasu,
15. kí wọn lè ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.
16. Àwọn mejila tí ó yàn náà nìyí: Simoni, tí ó sọ ní Peteru,
17. ati Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu àbúrò rẹ̀, ó sọ wọ́n ní Boanage, ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Àwọn ọmọ ààrá”;
18. ati Anderu, Filipi, Batolomiu, Matiu, ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, Tadiu, ati Simoni, ọmọ ẹgbẹ́ ìbílẹ̀ Kenaani,
19. ati Judasi Iskariotu ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
20. Lẹ́yìn náà, Jesu wọ inú ilé lọ, àwọn eniyan tún pé jọ tóbẹ́ẹ̀ tí òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò fi lè jẹun.
21. Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbọ́, wọ́n jáde lọ láti fi agbára mú un nítorí àwọn eniyan ń wí pé, “Orí rẹ̀ ti dàrú.”