1. Ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Àìwúkàrà tí à ń pè ní Àjọ̀dún Ìrékọjá.
2. Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe pa Jesu nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan.
3. Satani bá wọ inú Judasi tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.