Luku 17:18-37 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Kò wá sí ẹni tí yóo pada wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, àfi àlejò yìí?”

19. Jesu bá sọ fún un pé, “Dìde, máa lọ. Igbagbọ rẹ ni ó mú ọ lára dá.”

20. Àwọn Farisi bi Jesu nípa ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo dé. Ó dá wọn lóhùn pé, “Dídé ìjọba Ọlọrun kò ní àmì tí a óo máa fẹjú kí á tó ri pé ó dé tabi kò dé.

21. Kì í ṣe ohun tí àwọn eniyan yóo máa sọ pé, ‘Ó wà níhìn-ín’ tabi ‘Ó wà lọ́hùn-ún.’ Nítorí ìjọba Ọlọrun wà láàrin yín.”

22. Ó wá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí ẹ óo fẹ́ rí ọ̀kan ninu ọjọ́ dídé Ọmọ-Eniyan, ṣugbọn ẹ kò ní rí i.

23. Wọn yóo máa sọ pé, ‘Wò ó níhìn-ín’ tabi, ‘Wò ó lọ́hùn-ún’. Ẹ má lọ, ẹ má máa sáré tẹ̀lé wọn kiri.

24. Nítorí bí mànàmáná tíí kọ yànràn, tíí sìí tan ìmọ́lẹ̀ láti òkè délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo rí ní ọjọ́ tí ó bá dé.

25. Ṣugbọn dandan ni pé kí ó kọ́kọ́ jìyà pupọ, kí ìran yìí sì kẹ̀yìn sí i.

26. Àní bí ó ti rí ní àkókò Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé.

27. Nítorí ní àkókò Noa, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbeyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí di ọjọ́ tí Noa fi wọ inú ọkọ̀, ìkún-omi bá dé, ó bá pa gbogbo wọn rẹ́.

28. Bákan náà ni ó rí ní àkókò ti Lọti. Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń fúnrúgbìn, wọ́n ń kọ́lé,

29. títí di ọjọ́ tí Lọti fi jáde kúrò ní Sodomu, tí Ọlọrun fi rọ̀jò iná ati òkúta gbígbóná lé wọn lórí, tí ó pa gbogbo wọn rẹ́.

30. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ọjọ́ tí Ọmọ-Eniyan bá yọ dé.

31. “Ní ọjọ́ náà, bí ẹnìkan bá wà lórí ilé, tí àwọn nǹkan rẹ̀ wà ninu ilé, kí ó má sọ̀kalẹ̀ lọ kó o. Bákan náà ni ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sílé.

32. Ẹ ranti iyawo Lọti

33. Ẹni tí ó bá ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, yóo gbà á là.

34. Mo sọ fun yín, ní ọjọ́ náà, eniyan meji yóo sùn lórí ibùsùn kan, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.

35. Àwọn obinrin meji yóo máa lọ ògì, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. [

36. Àwọn ẹni meji yóo wà ní oko, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.”]

37. Wọ́n bi í pé, “Níbo ni, Oluwa?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn igún ń péjọ sí.”

Luku 17