25. “Ní gbogbo àkókò yìí, èyí ẹ̀gbọ́n wà ní oko. Bí ó ti ń bọ̀ tí ó ń súnmọ́ etílé, ó gbọ́ ìlù ati ijó.
26. Ó pe ọmọde kan, ó wádìí ohun tí ń ṣẹlẹ̀.
27. Ọmọ yìí bá sọ fún un pé, ‘Àbúrò rẹ dé, baba rẹ sì pa mààlúù tí ó sanra, ó se àsè nítorí tí àbúrò rẹ pada dé ní alaafia.’
28. Inú bí èyí ẹ̀gbọ́n, ó bá kọ̀, kò wọlé. Ni baba rẹ̀ bá jáde lọ láti lọ bẹ̀ ẹ́.