Luku 1:46-56 BIBELI MIMỌ (BM)

46. Nígbà náà ni Maria sọ pé,“Ọkàn mi gbé Oluwa ga,

47. ẹ̀mí mi yọ̀ sí Ọlọrun, Olùgbàlà mi,

48. nítorí ó ti bojúwo ipò ìrẹ̀lẹ̀ iranṣẹbinrin rẹ̀.Wò ó! Láti ìgbà yìí lọgbogbo ìran ni yóo máa pè mí ní olóríire.

49. Nítorí Olodumare ti ṣe ohun ńlá fún mi,Mímọ́ ni orúkọ rẹ̀;

50. àánú rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìranfún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

51. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ fi agbára rẹ̀ hàn,ó tú àwọn tí ó gbéraga ninu ọkàn wọn ká.

52. Ó yọ àwọn ìjòyè kúrò lórí oyè,ó gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ga.

53. Ó fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ àwọn tí ebi ń pa,ó mú àwọn ọlọ́rọ̀ jáde lọ́wọ́ òfo.

54. Ó ran Israẹli ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́nígbà tí ó ranti àánú rẹ̀,

55. gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí ó ti ṣe fún àwọn baba wa:fún Abrahamu ati fún ìdílé rẹ̀ títí lae.”

56. Maria dúró lọ́dọ̀ Elisabẹti tó bíi oṣù mẹta, ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀.

Luku 1