1. “Bí ẹnìkan bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia, tí ó sì mú ẹran láti inú agbo ẹran rẹ̀ fún ẹbọ náà, kì báà jẹ́ akọ tabi abo, ó níláti jẹ́ èyí tí kò ní àbààwọ́n níwájú OLUWA.
2. Kí ó gbé ọwọ́ lé orí ẹran náà, kí ó sì pa á lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ. Kí àwọn alufaa ọmọ Aaroni da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sára pẹpẹ náà yípo.
3. Kí ó mú àwọn nǹkan wọnyi ninu ẹbọ alaafia náà, kí ó fi wọ́n rú ẹbọ sísun sí OLUWA: ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ ati ọ̀rá tí ó wà lára ìfun rẹ̀,