Lefitiku 27:10-19 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Kò gbọdọ̀ fi ohunkohun dípò rẹ̀, tabi kí ó pààrọ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ pààrọ̀ ẹran tí kò dára sí èyí tí ó dára, tabi kí ó pààrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára. Bí ó bá jẹ́ pé ó fẹ́ fi ẹran kan pààrọ̀ ẹran mìíràn, ati èyí tí wọ́n pààrọ̀, ati èyí tí wọ́n fẹ́ fi pààrọ̀ rẹ̀, wọ́n di mímọ́.

11. Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́ ni, tí eniyan kò lè fi rúbọ sí OLUWA, kí ẹni náà mú ẹran náà tọ alufaa wá,

12. kí alufaa wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iye tí alufaa bá pè é náà ni iye rẹ̀.

13. Ṣugbọn bí ẹni náà bá fẹ́ ra ẹran náà pada, yóo fi ìdámárùn-ún kún iye owó rẹ̀.

14. “Nígbà tí ẹnìkan bá ya ilé rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iyekíye tí alufaa bá pè é ni iye rẹ̀.

15. Bí ẹni tí ó ya ilé yìí sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ilé náà bá tó, yóo sì tún fi ìdámárùn-ún iye owó rẹ̀ lé e. Nígbà tí ó bá san owó ilé náà pada, ilé yóo di tirẹ̀.

16. “Bí ẹnìkan bá ya apá kan ninu ilẹ̀ tí ó jogún sọ́tọ̀ fún OLUWA, ìwọ̀n èso tí eniyan bá lè rí ká lórí ilẹ̀ náà ni wọn yóo fi díye lé e. Bí a bá lè rí ìwọ̀n Homeri baali kan ká ninu rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, iye rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka.

17. Bí ó bá jẹ́ pé láti ọdún jubili ni ó ti ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, iyekíye tí ilẹ̀ náà bá tó lójú yín kò gbọdọ̀ dín.

18. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún Jubili ni ó ya ilẹ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, alufaa yóo ṣírò iye tí ó tó, gẹ́gẹ́ bí iye ọdún tí ó kù kí ọdún Jubili mìíràn pé bá ti pẹ́ sí, ẹ óo ṣí iye owó ọdún tí ó dínkù kúrò lára iye ilẹ̀ náà.

19. Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA bá fẹ́ rà á pada, yóo san iye tí ó bá tó, yóo sì fi ìdámárùn-ún owó rẹ̀ lé e, ilẹ̀ náà yóo sì di tirẹ̀.

Lefitiku 27