33. Ṣugbọn bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Lefi kò bá lo ẹ̀tọ́ ìràpadà yìí, ẹni tí ó bá ra ilé náà lọ́wọ́ rẹ̀ ninu ìlú olódi, yóo jọ̀wọ́ ilé náà sílẹ̀ ní ọdún jubili, nítorí pé, àwọn ilé tí ó wà ní ìlú àwọn ọmọ Lefi jẹ́ ìní tiwọn láàrin àwọn eniyan Israẹli.
34. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ta ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti gbogbogbòò, tí ó wà ní àyíká àwọn ìlú wọn, nítorí pé, ogún tiwọn nìyí títí ayérayé.
35. “Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè bọ́ ara rẹ̀ mọ́, o níláti máa bọ́ ọ, kí ó sì máa gbé ọ̀dọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àlejò ati àjèjì.
36. O kò gbọdọ̀ gba èlé lọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn bẹ̀rù Ọlọrun rẹ, kí o sì jẹ́ kí arakunrin rẹ máa bá ọ gbé.
37. O kò gbọdọ̀ yá a ní owó kí o gba èlé, o kò sì gbọdọ̀ fún un ní oúnjẹ kí o gba èrè.
38. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ, tí ó mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi ilẹ̀ Kenaani fún ọ ati láti jẹ́ Ọlọrun rẹ.