12. Wọ́n tì í mọ́lé títí tí wọn fi mọ ohun tí OLUWA fẹ́ kí wọ́n ṣe sí i.
13. OLUWA sọ fún Mose pé,
14. “Mú ọkunrin tí ó ṣépè náà jáde kúrò láàrin ibùdó, kí gbogbo àwọn tí wọ́n gbọ́ nígbà tí ó ṣépè gbé ọwọ́ lé e lórí, kí gbogbo ìjọ eniyan sì sọ ọ́ ní òkúta pa.
15. Wí fún àwọn eniyan Israẹli pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé Ọlọrun rẹ̀ yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ nítorí rẹ̀.
16. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á. Gbogbo ìjọ eniyan yóo sọ ọ́ ní òkúta pa, kì báà jẹ́ àlejò, kì báà jẹ́ onílé; tí ó bá ṣá ti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á.
17. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa eniyan, pípa ni wọn yóo pa òun náà.