38. Àwọn ẹbọ wọnyi wà lọ́tọ̀ ní tiwọn, yàtọ̀ sí ti àwọn ọjọ́ ìsinmi fún OLUWA, ati àwọn ẹ̀bùn yín, ati àwọn ẹbọ ẹ̀jẹ́ yín, ati àwọn ọrẹ ẹbọ àtinúwá tí ẹ óo máa mú wá fún OLUWA.
39. “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti kórè àwọn èso ilẹ̀ yín tán, láti ọjọ́ kẹẹdogun oṣù keje lọ, kí ẹ máa ṣe àjọ àjọ̀dún OLUWA fún ọjọ́ meje; ọjọ́ kinni ati ọjọ́ kẹjọ yóo jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀.
40. Ní ọjọ́ kinni, ẹ óo mú ninu àwọn èso igi tí ó bá dára, ati imọ̀ ọ̀pẹ, ati ẹ̀ka igi tí ó ní ewé dáradára, ati ẹ̀ka igi wilo etí odò, kí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín fún ọjọ́ meje.
41. Ọjọ́ meje láàrin ọdún kan ni ẹ óo máa fi ṣe àjọ̀dún fún OLUWA; Ìlànà títí lae ni èyí jẹ́ fún arọmọdọmọ yín. Ninu oṣù keje ọdún ni ẹ óo máa ṣe àjọ àjọ̀dún náà.
42. Inú àgọ́ ni ẹ óo máa gbé fún gbogbo ọjọ́ meje náà; gbogbo ẹni tí ó bá jẹ́ ọmọ Israẹli ni ó gbọdọ̀ gbé inú àgọ́,