Lefitiku 20:25-27 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Nítorí náà, ẹ níláti mọ ìyàtọ̀ láàrin àwọn ẹran tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́; ati láàrin àwọn ẹyẹ tí ó mọ́ ati àwọn tí kò mọ́. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹyẹ tabi ẹranko kankan tabi àwọn ẹ̀dá alààyè tí ń káàkiri lórí ilẹ̀, tí mo ti yà sọ́tọ̀ fun yín pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́.

26. Ẹ níláti jẹ́ mímọ́ fún mi, nítorí pé, mímọ́ ni èmi OLUWA, mo sì ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn eniyan kí ẹ lè máa jẹ́ tèmi.

27. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tabi oṣó, pípa ni kí ẹ pa á; ẹ sọ wọ́n ní òkúta pa ni, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì wà lórí ara wọn.”

Lefitiku 20