Lefitiku 20:18-21 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Bí ọkunrin kan bá bá obinrin lòpọ̀ ní àkókò tí obinrin yìí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀, lílé ni kí wọ́n lé àwọn mejeeji kúrò ní àdúgbò, kí wọ́n sì yọ wọ́n kúrò láàrin àwọn eniyan wọn.

19. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bá arabinrin ìyá rẹ, tabi arabinrin baba rẹ lòpọ̀, nítorí pé, ìwà ìbàjẹ́ ni láàrin ẹbí. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

20. Bí ẹnìkan bá bá aya arakunrin baba rẹ̀ lòpọ̀, ohun ìtìjú ni ó ṣe sí arakunrin baba rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo sì fi orí ara wọn ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọn yóo kú láì bímọ.

21. Bí ọkunrin kan bá bá aya ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lòpọ̀, tabi aya àbúrò rẹ̀, ohun àìmọ́ ni, ohun ìtìjú ni ó sì ṣe sí ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò rẹ̀, àwọn mejeeji yóo kú láì bímọ.

Lefitiku 20