Lefitiku 19:22-30 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Alufaa yóo fi àgbò ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi náà ṣe ètùtù fún un níwájú OLUWA nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, OLUWA yóo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì í.

23. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà, tí ẹ bá sì gbin oríṣìíríṣìí igi eléso fún jíjẹ, ẹ ka gbogbo èso tí wọ́n bá so fún ọdún mẹta ti àkọ́kọ́ sí aláìmọ́; èèwọ̀ ni, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.

24. Ní ọdún kẹrin, ẹ ya gbogbo àwọn èso náà sọ́tọ̀ fún rírú ẹbọ ọpẹ́ sí OLUWA.

25. Ṣugbọn ní ọdún karun-un, ẹ lè jẹ èso wọn, kí wọ́n lè máa so sí i lọpọlọpọ. Èmi ni OLUWA.

26. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ lọ máa woṣẹ́, tabi kí ẹ gba àjẹ́. Diut 18:10

27. Ẹ kò gbọdọ̀ gé ẹsẹ̀ irun orí yín tabi kí ẹ gé ẹsẹ̀ irùngbọ̀n yín.

28. Ẹ kò gbọdọ̀ ya ara yín lábẹ nítorí òkú, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fín ara yín rárá. Èmi ni OLUWA.

29. “Ẹ kò gbọdọ̀ ba ọmọbinrin yín jẹ́, nípa fífi ṣe aṣẹ́wó; kí ilẹ̀ náà má baà di ilẹ̀ àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà burúkú.

30. Ẹ gbọdọ̀ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ wọ ilé mímọ́ mi. Èmi ni OLUWA.

Lefitiku 19