Lefitiku 10:15-20 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Nígbà tí wọ́n bá mú ọ̀rá ẹran wá fún ẹbọ sísun, tí wọ́n mú itan ẹran tí wọ́n fi rúbọ, ati igẹ̀ àyà rẹ̀ fún ẹbọ fífì níwájú OLUWA, yóo máa jẹ́ tìrẹ, ati ti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìpín yín títí ayé, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ.”

16. Mose fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí nípa ewúrẹ́ tí wọ́n fi rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ó sì rí i pé wọ́n ti dáná sun ún. Inú bí i sí Eleasari ati Itamari, àwọn ọmọ Aaroni tí wọ́n ṣẹ́kù, ó ní,

17. “Kí ló dé tí ẹ kò fi jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ní ibi mímọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé, ohun tí ó mọ́ jùlọ ni, tí ó sì jẹ́ pé ẹ̀yin ni OLUWA ti fún, kí ẹ lè máa ru ẹ̀ṣẹ̀ ìjọ eniyan yìí, kí ẹ sì máa ṣe ètùtù fún wọn níwájú OLUWA.

18. Wọn kò sì tíì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sinu ibi mímọ́, gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ.”

19. Aaroni dá Mose lóhùn pé, “Wò ó! Lónìí ni wọ́n rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ sísun wọn sí OLUWA, sibẹsibẹ irú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí mi. Bí ó bá jẹ́ pé mo ti jẹ ẹran ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ lónìí ni, ǹjẹ́ ẹbọ náà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA?”

20. Nígbà tí Mose gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, inú rẹ̀ rọ̀.

Lefitiku 10