22. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n pa, nítorí pé Ọlọrun ni ó jà fún wọn; wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn títí tí àwọn ará Asiria fi kó wọn lẹ́rú.
23. Ìdajì ẹ̀yà Manase ń gbé Baṣani, wọ́n pọ̀ pupọ; wọ́n tàn ká títí dé Baali Herimoni, Seniri, ati òkè Herimoni.
24. Àwọn Olórí ìdílé wọn nìwọ̀nyí: Eferi, Iṣi, Elieli, ati Asirieli; Jeremaya, Hodafaya ati Jahidieli, akikanju jagunjagun ni wọ́n, wọ́n sì jẹ́ olókìkí ati olórí ní ilé baba wọn.
25. Ṣugbọn àwọn ẹ̀yà náà ṣẹ Ọlọrun baba wọn, wọ́n pada lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa tí àwọn tí Ọlọrun parun nítorí wọn ń bọ.