12. ati àwòrán gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn láti ṣe sinu àgbàlá ilé OLUWA, ati ti àwọn yàrá káàkiri, àwọn ilé ìṣúra tí yóo wà ninu ilé Ọlọrun, ati ti àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n o máa kó ohun tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA pamọ́ sí.
13. Dafidi tún fún un ní ìwé ètò pípín àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, ati ètò gbogbo iṣẹ́ ìsìn inú ilé OLUWA, ti àwọn ohun èlò fún ìsìn ninu ilé OLUWA;
14. àkọsílẹ̀ ìwọ̀n wúrà fún gbogbo ohun èlò wúrà fún ìsìn kọ̀ọ̀kan, ti ìwọ̀n fadaka fún gbogbo ohun èlò fadaka fún ìsìn kọ̀ọ̀kan,