Kronika Kinni 25:4-7 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Àwọn ọmọ Hemani ni: Bukaya, Matanaya, Usieli, Ṣebueli, ati Jerimotu, Hananaya, Hanani, Eliata, Gidaliti, ati Romamiti Eseri, Joṣibekaṣa, Maloti, Hotiri, ati Mahasioti.

5. Ọmọ Hemani, aríran ọba, ni gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí Ọlọrun ṣe láti gbé Hemani ga; Ọlọrun fún un ní ọmọkunrin mẹrinla ati ọmọbinrin mẹta.

6. Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n máa ń lu aro ati hapu, tí wọ́n sì ń tẹ dùùrù lábẹ́ àkóso baba wọn ninu ìsìn ninu ilé Ọlọrun. Ṣugbọn Asafu, Jedutuni, ati Hemani wà lábẹ́ àkóso ọba.

7. Àpapọ̀ wọn pẹlu àwọn arakunrin wọn, tí a ti kọ́ ní orin kíkọ sí OLUWA, ati lílo ohun èlò orin, jẹ́ ọọdunrun ó dín mejila (288).

Kronika Kinni 25