7. Kami ni baba Akani; Akani yìí ni ó kó wahala bá Israẹli, nítorí pé ó rú òfin nípa àwọn ohun ìyàsọ́tọ̀.
8. Etani ni ó bí Asaraya.
9. Àwọn ọmọ Hesironi ni Jerameeli, Ramu ati Kelubai.
10. Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda,
11. Nahiṣoni ni baba Salima; Salima ni ó bí Boasi,
12. Boasi bí Obedi, Obedi sì bí Jese.