46. Kalebu tún ní obinrin kan tí ń jẹ́ Efa, ó bí ọmọ mẹta fún un: Harani, Mosa ati Gasesi. Harani bí ọmọ kan tí ń jẹ́ Gasesi.
47. Àwọn ọmọ Jadai nìwọ̀nyí: Regemu, Jotamu, ati Geṣani, Peleti, Efa ati Ṣaafu.
48. Kalebu tún ní obinrin mìíràn tí ń jẹ́ Maaka. Ó bí ọmọ meji fún un: Ṣeberi ati Tirihana.
49. Maaka yìí kan náà ni ó bí Ṣaafu, baba Madimana, tí ó tẹ ìlú Madimana dó, ati Ṣefa, baba Makibena ati Gibea, àwọn ni wọ́n tẹ ìlú Makibena ati ìlú Gibea dó.Kalebu tún bí ọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Akisa.
50. Àwọn ìran Kalebu yòókù ni: àwọn ọmọ Huri àkọ́bí Efurata, iyawo Kalebu: ati Ṣobali, baba Kiriati Jearimu;
51. Salima, baba Bẹtilẹhẹmu, ati Harefu baba Betigaderi.
52. Ṣobali baba Kiriati Jearimu ni baba gbogbo àwọn ará Haroe, ati ìdajì àwọn tí ń gbé Menuhotu,
53. Òun náà ni baba ńlá gbogbo àwọn ìdílé tí ń gbé Kiriati Jearimu, àwọn ìdílé bíi Itiri, Puti, Ṣumati, ati Miṣirai; lára wọn ni àwọn tí wọn ń gbé ìlú Sora ati Eṣitaolu ti ṣẹ̀.