Kronika Kinni 19:16-18 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé àwọn ará Israẹli ṣẹgun àwọn, wọ́n ranṣẹ lọ pe àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n wà ni ìkọjá odò Yufurate, wọ́n sì fi wọ́n sí abẹ́ Ṣobaki, balogun Hadadeseri.

17. Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo ọmọ ogun Israẹli jọ, wọ́n rékọjá odò Jọdani, wọ́n lọ dojú kọ ogun Siria, àwọn ọmọ ogun Siria bá bẹ̀rẹ̀ sí bá Dafidi jagun.

18. Àwọn ogun Siria sá níwájú Israẹli. Dafidi pa ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn tí wọn ń wa kẹ̀kẹ́-ogun ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ọmọ ogun ẹlẹ́sẹ̀, ó sì pa Ṣobaki olórí ogun Siria.

Kronika Kinni 19