11. Dafidi yà wọ́n sí mímọ́ fún OLUWA, fún iṣẹ́ ìsìn pẹlu àwọn fadaka ati wúrà tí ó gbà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun: àwọn bíi Edomu ati Moabu, Amoni, Filistini ati Amaleki.
12. Abiṣai, ọmọ Seruaya, ṣẹgun àwọn ará Edomu ní àfonífojì Iyọ̀, ó pa ẹgbaa mẹsan-an (18,000) ninu wọn.
13. Ó fi àwọn ọmọ ogun sí Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì di iranṣẹ Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.
14. Dafidi jọba lórí gbogbo Israẹli, ó ń dá ẹjọ́ òtítọ́, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ fún gbogbo àwọn eniyan.
15. Joabu, ọmọ Seruaya, ni Balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni olùtọ́jú àwọn àkọsílẹ̀.
16. Sadoku, ọmọ Ahitubu ati Ahimeleki ọmọ Abiatari ni alufaa.